Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti kẹdun iku amugbalẹgbẹ rẹ lori ọrọ ẹsin Kristẹni, Ọmọwe Samuel Oluṣẹgun Adedayọ, to si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni to gbagbọ gidi ninu ẹsin naa.
O ni Ọmọwe Adedayọ jẹ akikanju to farabalẹ, ẹni to tun ni iwa tutu ati itẹriba, eyi to mu ki wọn yan an lati di ipo naa mu, paapaa gẹgẹ bi ipa rere to ti ko lawujọ Kristẹni.
AbdulRazaq jẹ ko di mimọ ninu atẹjade ibanikẹdun to gbe jade lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye wi pe ọkan pataki lara awọn to nigbagbọ ninu afojusun ijọba yii nipa 'OTOGẸ' ni oloogbe naa.
No comments:
Post a Comment