Ọrọ buruku toun tẹrin-in nigba ti ọkunrin kan, Festus James to pe ara rẹ ni Wolii fipa ba obinrin alaboyun kan laṣepọ, pẹlu ẹtanjẹ wi pe oun fẹẹ gbadura itusilẹ fun un, ko le bọ kuro lọwọ ẹmikẹmi to n da a laamu.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ilu Ibadan ni Festus ti kuro, to si lọ si abule Agbabu to wa nijọba ibilẹ Odigbo, ipinlẹ Ondo lati lọ ṣe isọji ọlọjọ mẹta níbẹ.
Ṣọọṣi kan to wa ninu abule naa la gbọ pe Festus lọ, to si ni Olọrun lo ran oun wa sibẹ lati wa a ṣe isọji ọlọjọ mẹta lati tu awọn eeyan silẹ kuro ninu igbekun, ti wọn si gba laaye, koda, wọn tun fun un ni yara ati ọfiisi ti yoo lo fun ọjọ mẹta ọhun.
Ibi ti isọji naa ti bẹrẹ lọjọ akọkọ la gbọ pe Festus ti foju gan-ni ọmọbinrin, ọmọ ọdun mejilelogun kan, to loyun oṣu mẹjọ sinu. Nibi to ti n waasu rẹ lo ti sọ fun obinrin naa pe ko duro ri oun lẹyin ipade, nitori toun fẹẹ ṣe itusilẹ ara-ọtọ fun un.
Lẹyin ti wọn ṣetan la gbọ pe obinrin naa lọ ba a ni ọfiisi, ti wọn si ni ṣe ni Festus bọ pata ẹ, to si ko ibasun fun un karakara. Wọn ni alaboyun naa ko le pariwo, nitori pe agbara rẹ ko ka Festus, ṣugbọn bo ṣe kuro nibẹ lo ti pariwo sita fawọn eeyan.
Loju ẹsẹ ni wọn lawọn eeyan ti sare lọ sibẹ, ti wọn si pariwo lee lori. Nibẹ lo ti rawọ ẹbẹ pe ki wọn daṣọ aṣiri boun, nitori pe iṣẹ eṣu ni.
Ibẹ ni wọn gba mu de teṣan ọlọpaa, nibi to ti jẹwọ pe lotitọ ni, ati pe oun ko fipa tipa ba alaboyun naa laṣepọ, bi ko ṣe pe awọn jọ gbadun ara wọn ni.
No comments:
Post a Comment