Adérìnókùn tún ṣe ìrànwọ́ fún ìdásílẹ̀ ọ́fíìsì àgbérìn àwọn agbejọ́rò l'Ógùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 26, 2021

Adérìnókùn tún ṣe ìrànwọ́ fún ìdásílẹ̀ ọ́fíìsì àgbérìn àwọn agbejọ́rò l'Ógùn


Gbajugbaja alaanu ati oludasilẹ ajọ alaanu Olumide and Stephanie Aderinokun Foundation nni, Oloye Olumide Aderinokun tun ti ṣe iranlọwọ alailẹgbẹ fun idasilẹ ọfiisi agberin fawọn agbẹjọro, iyẹn 'Mobile Lawyers' Office' kaakiri ipijnlẹ Ogun.
 
Ọjọbọ, Tọside ana la gbọ pe Oloye Aderinokun, ẹni to tun jẹ Akinruyiwa tilu Owu, Abẹokuta gbe owo nla ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin (₦700,000) naira kalẹ fun kikọ ọfiisi ọhun.

Agba ati alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP) naa, nigba to n sọrọ sọ pe lati le jẹ ki awọn araalu jẹ nafaani eto idajọ to peregede, lo jẹ koun dide iranlọwọ fawọn amofin, ki wọn le maa gbẹnusọ fawọn araalu lọna eto idajọ.

O tẹsiwaju pe erongba oun tun ni fawọn ẹlẹwọn lati jẹ anfaani idajọ ododo, paapaa awọn ti awọn ọlọpaa fiya jẹ lọna ti ko ba ofin mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI