Wọ́n bá òkú òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè tí wọ́n jígbé lórí omi l'Ógùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 31, 2021

Wọ́n bá òkú òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè tí wọ́n jígbé lórí omi l'Ógùn


Ileeṣẹ aṣọbode orilẹ-ede yii ti sọ pe awọn ti ṣawari oku ọkan lara awọn oṣiṣẹ wọn ti wọn jigbe lọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ yii lori omi kan nijọba ibilẹ Guusu Yewa, ipinlẹ Ogun.
 
Ori odo kan to wa nitosi abule Fagbohun la gbọ pe wọn ti ṣawari oku oṣiṣẹ aṣọbode naa ti wọn lawọn onifayawọ jigbe.
 
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ọga aṣọbode ti Federal Operations Unit (FOU), Zone A, to wa ni Ikeja, l'Ekoo, Hussein Kẹhinde Ejibunu, sọ pe ọwọ to le lawọn yoo maa fi mu ọrọ awọn onifayawọ lakooko yii, ati pe ṣe ni wọn yoo maa doju ibọn kọ wọn ni gbogbo igba ti wọn ba ti fẹẹ kogun ja wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI