Wàhálà débá ilé iṣẹ́ Fesibuuku, Wasaapu àti Insitagiraamu, làwọn èèyàn bá lópin ayé ti dé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 4, 2021

Wàhálà débá ilé iṣẹ́ Fesibuuku, Wasaapu àti Insitagiraamu, làwọn èèyàn bá lópin ayé ti dé


Ko si ọrọ meji to n jade lẹnu awọn eeyan kaakiri agbaye lakooko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan to yatọ si pe 'opin aye ti de', iyẹn lori bi awọn ileeṣẹ ikansira-ẹni ati abanidọrẹ pẹlu ibara-ẹni-sọrọ to gbajumọ lagbaye, iyẹn Fesibuuku, Wasaapu ati Insitagiraamu ṣe kuro lori ikanni ayelujara.

Nnkan bi aago marun-un ku iṣeju mọkanlelogun ni gbogbo awọn ikanni ayelujara naa kuro lori afẹfẹ patapata kaakiri agbaye, ti ko si tii sẹni to le sọ pato ohun to ṣokunfa rẹ.
 
Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ to n ṣakoso awọn ikanni ayelujara naa, Mark Zuckerberg ti fidi rẹ mulẹ pe loootọ lawọn n koju awọn iṣoro kan, ati pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lori rẹ, lati rii pe awọn pada sori ayelujara.

Ori ikanni ayelujara ti Twitter ni Zuckerberg ti sọrọ naa laipẹ yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI