TESCOM bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn olùkọ́ tuntun ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 25, 2021

TESCOM bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn olùkọ́ tuntun ni Kwara


Ọjọru, Wẹside si Ọjọbọ, Tọside ọsẹ yii, iyẹn ọjọ kẹtadinlọgbọn ati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu yii ni ajọ Teaching Service Commission, ẹka tipinlẹ Kwara yoo ṣe idanilẹkọọ fun gbogbo awọn olukọ sile ẹkọ girama ti wọn ṣẹṣẹ gba wọle patapata.

Awọn olukọ ẹgbẹrun meji ti ijọba ipinlẹ Kwara ṣẹṣẹ gba la gbọ pe wọn yoo jẹ anfaani idanilẹkọọ yii, lojuna lati le mọ nipa ọna ti wọn yoo gbe eto ẹkọ gba bi wọn ba bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹu.

Wọn ni ajọ TESCOM ati ẹgbẹ awọn olori ileewe, iyẹn All Nigeria Federation of Principals of Secondary Schools (ANCOPSS), ni wọn gbe eto idanilẹkọọ naa kalẹ.

Ile-ẹkọ Queen Elizabeth College, to wa niluu Ilọrin ni wọn yoo ti ṣide eto naa l'Ọjọru, Wẹside, eyi ti alaga TESCOM, Mallam Bello Tauheed yoo ti dari rẹ.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin TESCOM, Ọgbẹni Peter Amogbojaiye fi sita, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti jẹ ko di mimọ pe awọn olukọ ni aarin gbungbun Kwara yoo gba idanilẹkọọ ti wọn ni ile-ẹkọ girama tijọba, Government Secondary School to wa niluu Ilọrin.
 
O sọ pe awọn olukọ lati ijọba ibilẹ Guusu Kwara yoo gba idanilẹkọọ ti wọn ni Government Secondary School, Omu-Aran ati Ọffa Grammar School, to wa ni Ọffa.

Siwaju sii lo sọ pe idanilẹkọọ fawọn olukọ ni Ariwa Kwara yoo waye Government Unity Secondary School, Kaiama; Baptist Grammar School, Okuta ati Lafiagi Secondary School, to wa ni Lafiagi l'Ọjọbọ, Tọside.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI