Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ti ṣetan lati bẹrẹ sii san owo oṣu tuntun fun gbogbo awọn oṣiṣẹ jakejado, pẹlu ẹkunwo to ba yẹ lasiko, ati pe ko si ọrọ ojusaaju kankan mọ.
Ọjọ Ẹti, Furaidee ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe ipade papọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ naa, nibi ti wọn ti tọwọ bọwe adehun nipa ọrọ owo oṣu tuntun tawọn oṣiṣẹ yoo maa gba, ati ẹkunwo fawọn to ṣẹṣẹ gba igbega.
Nibẹni Gomina AbdulRazaq ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe inu oṣu keji, ọdun yii lawọn bẹrẹ sisan owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ lati ipele kin-in-ni si ipele kẹfa, sibẹ, o lawọn yoo bẹrẹ sii san owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ lati ipele keje titi de ipele kẹtadinlogun.
Lara awọn to wa nibẹ lawọn aṣoju ẹgbẹ awọn oṣisṣẹ, ti alaga wọn, Kọmureedi Issa Ore lewaju wọn, Alaaja Afusat Afọlabi; Gomina AbdulRahman AbdulRazaq; Sẹnetọ Ibrahim Yahya Oloriẹgbẹ; Ọnọrebu Florence Ọlasumbọ Oyeyẹmi.
Awọn miran ni Kọmureedi Akinwunmi Akinṣọla; Saliu Suleiman; Kọmureedi Joseph Tunde; ati Yusuf Ibrahim Amuda.
No comments:
Post a Comment