Oríire ńlá, SMEDAN gbé owó ńlá kálẹ̀ fáwọn ẹgbẹ́ alájẹṣẹ́kù n'ìpínlẹ̀ Ògùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, October 16, 2021

Oríire ńlá, SMEDAN gbé owó ńlá kálẹ̀ fáwọn ẹgbẹ́ alájẹṣẹ́kù n'ìpínlẹ̀ Ògùn


Lojuna lati jẹ ki ounjẹ pọ lọpọ yanturu, fun igbayegbadun araalu, ileeṣẹ to n bojuto idagbasoke awọn olokoowo kekere ati kereje lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn Small and Medium Enterprises Development Agency of Nigeria (SMEDAN), ti gbe iranlọwọ owo dide kalẹ fawọn ẹgbẹ alajẹṣẹku nipinlẹ Ogun.

Gbọgan TECH-HUB to wa loju ọna Abẹokuta silu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun ni eto naa ti waye lonii, nibi aṣekagba idanilẹkọọ ọlọjọ mẹta gbako ti wọn ṣe fawọn ẹgbẹ alajẹṣẹku naa.

Idanilẹkọọ naa to bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii, lo pari lonii, Ọjọbọ, Tọside pẹlu eto aṣekagba, nibi ti wọn ti fi ẹbun owo to din diẹ lẹgbẹrun lọna ọọdunrun (288,750.00) naira ṣe iranlọwọ fun gbogbo wọn.

Nigba to n sọrọ, ọga agba fun ileeṣẹ SMEDAN nilẹ Yoruba, Ọnọrebu Tokunbọ Ọṣhin sọ pe “ti ounjẹ ba ti kuro ninu iṣẹ, iṣẹ ti bu ṣe niyẹn. Iye yoowu ti ijọba apapọ le fi ranṣẹ si wọn lati fi ṣe owo, ni ki wọn jẹ ko lọ sori owo. Owo ti wọn gba kii ṣe lati fi ṣe ayẹyẹ tabi pati.

“Idi ti a fi pinnu lati gbe eto yii kalẹ fawọn ẹgbẹ alajẹṣẹku ni lati le tọpinpin bi wọn ṣe na owo naa nigba ti wọn ba gba a. A ti mọ pe ajọwo wa nibẹ lati le mọ ohun to ku to yẹ ka tun ṣe. Ipele-ipele la gbe eto yii kalẹ, idi niyi to fi jẹ pe iwọnba lawọn ti ẹ ri nibi, bi a ṣe pari eyi, awọn miran yoo tun bẹrẹ ti wọn laipẹ.

“Bi a ṣe n ṣee nibi naa la tun n ṣe ni Ondo, Ọyọ, Ọṣun, Bauchi, Port Harcourt ati kaakiri Naijiria.”

Ọkan lara awọn to jẹ anfaani yii, Pasitọ Jayesinmi Ọlajide nigba to n sọrọ sọ pe inu oun dun lati jẹ anfaani rẹpeẹteẹ nibi idanilẹkọọ naa, o ni ko rọrun boun ṣe n wa lojoojumọ, ṣugbọn toun ko kabamọ lati jẹ ọkan lara awọn akopa nibi idanilẹkọọ ọhun.

Ọkunrin naa tẹsiwaju pe kii ṣe nipa ti owo tawọn gba nikan, bi ko ṣe nipa imọ ati ẹkọ tawọn tun ri kọ nibẹ, to si ni iyẹn gan-an ni ojulowo anfaani wọn.

Ninu ọrọ rẹ, o ni gbogbo awọn ẹkọ tawọn ri kọ lo ṣe anfaani pupọ, eyi to lawọn yoo mu lo fun idagbasoke okoowo wọn lẹka iṣẹ agbẹ ati ọgbin, pẹlu awọn iṣẹ miran tawọn ba tun dawọ le.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI