Oríire nlá: Gbajúmọ̀ Olóyè gbé ètò ẹ̀yáwó ìrọ̀rùn kalẹ̀ fáwọn ọlọ́jà l'Ógùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 7, 2021

Oríire nlá: Gbajúmọ̀ Olóyè gbé ètò ẹ̀yáwó ìrọ̀rùn kalẹ̀ fáwọn ọlọ́jà l'Ógùn


Ṣẹnkẹn bayii ni inu pupọ awọn ọlọja nipinlẹ Ogun, paapaa nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode ati Owode n dun lori bi gbajumọ oloye nni, Oloye Olumide Aderinokun ṣe gbe eto ẹyawo ti ko wọpọ kalẹ fun gbogbo wọn lati jẹ anfaani.

Ẹsẹ ko gbero rara ni agbegbe kan ti wọn pe ni Iyana-Mọṣuari to wa nilu Abẹokuta, to jẹ olu-ilu ipinlẹ naa, nibi ti eto ọhun ti waye.

Ọlọja ti ko din ni ọgọrun-un ni wọn jẹ anfaani ẹyawo naa, eyi ti a gbọ pe ko ni ele ninu rara, gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ti wọn si ni bi wọn ṣe gba owo naa ko ni ẹlẹyamẹya ninu rara.


Fọọmu la gbọ pe Oloye Aderinokun gbe jade lorukọ ajọ alaanu rẹ, Olumide and Stephanie Aderinokun Foundation fun awọn ọlọja naa, ti a si gbọ pe awọn to peregede ni wọn jẹ anfaani naa.

Pupọ awọn to jẹ anfaani yii ni wọn n dupẹ wi pe awọn ri anfaani ẹyawo ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira naa gba.

Wọn ni owo naa yoo jẹ ki ọja wọn ati ọrọ aje wọn tẹsiwaju, nitori pe diẹdiẹ lawọn yoo maa da owo naa pada fun oṣu mẹfa gbako.

Nigba to n sọrọ lori idi pataki to fi gbe eto ẹyawo naa kalẹ, Oloye Aderinokun sọ pe:


"Nigba ti mo jade du ipo ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin, lara awọn ohun to n bawọn eeyan lọkan jẹ ni ti owo gbọmulelanta ti wọn n gba. Wọn ni awọn n fẹ eto ẹyawo ti yoo mu irọrun ba eto ọrọ aje ati okoowo wọn.

"Wọn ni bi awọn to n gbe ẹyawo naa jade ṣe maa n ṣe wọn, kii tẹ wọn lọrun, ati pe ele ti wọn maa n fi sori awọn owo naa ti maa n pọ ju agbara wọn lọ. Mo ṣeleri fun wọn nigba naa wi pe maa ṣe iranlọwọ fun wọn lagbara mi.

"Awọn nnkan ti mo fẹẹ ṣe pọ, eyi lo jẹ ki n da ajọ alaanu silẹ lati maa fi ṣe iranlọwọ fawọn araalu. Lara rẹ si ni ti eto ẹyawo ti a bẹrẹ yii. Mo nigbagbọ pe nigba ti ọdun yii yoo ba fi pari, a maa ti ṣe idaji eto ẹyawo naa sita.

"Bi wọn ba ṣe daadaa, a tun maa fi kun owo naa bi wọn ba fẹẹ gba owo miran. Eyi ti a n ṣe lonii, ni ti awọn ara ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode ati Ọdẹda, nigba to ba ya, a maa bẹrẹ nijọba ibilẹ Ifọ ati Ewekoro. Nigba ti yoo ba fi di oṣu kejila, awọn ara ijọba ibilẹ Abẹokuta North ati South naa yoo jẹ anfaani yii. Ọgọrun kan lawọn to jẹ anfaani yii.

"Fọọmu la gbe jade, ti a fi mu awọn ọlọja naa. Awọn ti a rii pe wọn peregede la mu. Oṣu mẹfa gbako ni wọn fi maa daa pada. Bi wọn ba ṣe daadaa, ti wọn si tete da owo naa pada, a maa fi kun un fun wọn."

 








No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI