Ọmọọba Fágbèmí di alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 17, 2021

Ọmọọba Fágbèmí di alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní Kwara


Ṣe lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara lonii, ọjọ Abamẹta, Satide gba ilu ati ijo, ni kete ti wọn pari ipade gbogboogbo wọn to waye nilu Ilọrin, nigba ti Ọmọọba Sunday Fagbemi jawe olubori gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ naa.
 
Nibẹ ni Fagbemi ti ṣe ileri wi pe oun yoo ṣiṣẹ papọ fun alaafia ati iṣọkan ẹgbẹ, toun yoo si jẹ apẹẹrẹ rere ati awokọṣe fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ to n bọ lẹyin, paapaajulọ, awọn ọmọ ẹgbẹ miran.
 
Fagbemi sọ pe gbogbo awọn to ba nii ṣe loun yoo ba ṣiṣẹ papọ lati rii pe APC duro ṣinṣin.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹyin Gomina AbdulRahman AbdulRazaq pẹlu akọsilẹ rere ni Ọmọọba Fagbemi to jawe olubori yii.











No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI