Boroboro ni baale ile, ẹni ọdun mejilelaadọta kan, Adebayọ Akinrinoye n ka lagọ ọlọpaa lọsẹ to kọja yii, nigba tọwọ palaba rẹ segi, to si n bẹbẹ pe ki wọn foju aanu wo oun.
AWIKONKO gbọ pe ọmọ bibi inu rẹ, ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni Adebayọ n ko ibasun fun latigba to ti wa lọmọ ọdun mẹrinla, eyi to jẹ ọdun meji gbako.
Ọmọ naa taa forukọ bo laṣiri la gbọ pe o gba teṣan ọlọpaa lọ lati lọ fi ẹjọ sun nibẹ wi pe baba oun n ba oun lajọṣepọ, ati pe o ti su oun, ti baba naa ko si fẹẹ gbọ.
Wọn lẹsẹkẹsẹ lawọn ọlọpaa ti lọ gbe Adebayọ nile ẹ to wa ni Kabiru Close, Idi Ọparun, Mọtgun, Agbado nipinlẹ Ogun, iyẹn lọjọ kẹtalelogun, oṣu to kọja yii.
Adebayọ sọ pe lotitọ lo jẹ pe ọmọ ọdún mẹrinla ni ọmọ oun naa wa, ti oun ti n ko ibasun fun un karakara lai mọ pe aṣiri maa pada tu.
O lọmọ naa ti sọ pe koun jawọ, ṣugbọn eṣu to fẹẹ fi oun ṣe ẹlẹya lo di oun loju ati iye, toun ko fi mọ nnkan toun n ṣe.
No comments:
Post a Comment