Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Ayọdele ti sọ pe ki gomima ipinlẹ Benue, Samuel Ortom lọ fi ọkan ara rẹ balẹ nitori pe Ọlọrun yoo tu aṣiri awọn to n fi iku waa kaakiriti ero ọta ko si nii ṣe lori ẹ.
Ojiṣẹ Ọlọrun naa lo sọrọ yii nigba to n sọrọ lori ẹsun ti GOmina Ortom fi kan awọn kan wi pe wọn n fiku wa oun kaakiri, nitori ọrọ eto aabo toun mu lokunkundun nipinlẹ oun.
Gomina Ortom sọ ni gbagede ti Sesugh Maria Pilgrimage Center Ayati, to wa nijọba ibilẹ Gwer East, ipinlẹ Benue wi pe awọn kan n fiku wa oun kaakiri, ati pe oun ko nii pada sẹyin lati rii pe oun ṣe aṣeyọri, toun si jẹ ki ipinlẹ naa wa ni ipo to dara lai nii ṣe pẹlu oniruuru idunkoko toun ti n gba.
Wolii Ayọdele jẹ ko di mimọ pe awọn to wa layika gomina naa ati awọn to mọ dijudiju ni wọn n gbero ọtẹ lee lori, ti wọn si n wa ko ku danu, ṣugbọn to sọ pe Ọlọrun yoo da erongba wọn ru lati ma ṣe jẹ ki ipinnu wọn wa si imuṣẹ.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:
"Gomina ipinlẹ Benue, ọmọ Ọlọrun ni ẹ, gbogbo awọn to n gbiyanju lati pa ẹ ni aṣiri wọn maa tu, Ọlọrun ti n ṣe laabo fun ẹ, ko si sohun ti yoo ṣe ẹ. Loootọ ni wọn fẹẹ pa ẹ, gẹgẹ bi mo ṣe jkilọ fun ẹ tẹlẹ, ṣugbọn Ọlọrun yoo doju ti wọn, waa pari saa iṣakoso rẹ layọ, oju yoo si ti wọn.
"Gbogbo awọn to wa nidi ẹ ni aṣiri wọn yoo tu, nitori pe ayanfẹ Ọlọrun ni ẹ, o ti n ṣakoso daadaa, o si fọkan jin, Ọlọrun wa pẹlu ẹ. Awọn ti n gbimọ naa wa nipinlẹ rẹ, awọn ti o mọ ni, ṣugbọn Ọlọrun ni alaabo rẹ.
"Ohun ti o nilo lati ṣe ni pe ki o tubọ sunmọ Ọlọrun, ki o si maa kiyesari gbogbo ibi ti o ba n lọ, waa pari iṣakoso rẹ daadaa."
No comments:
Post a Comment