L'Ọjọbọ, Tọside ana, ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq gba awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lamọran lati mura giri sọrọ eto aabo, ati pe ki wọn wa ni ojulalakan-fi-n-ṣọri lati rii pe eto aabo dohun igbagbe patapata lawujọ wa.
Gomina AbdulRazaq lo parọwa yii nibi ayẹyẹ eto ikẹkọọjade awọn akẹkọọ ile-ẹkọ eto ilera ti Nigerian Navy College of Health Sciences (NNCHS), to wa nilu Ọffa, ipinlẹ Kwara.
Ọgbẹni Kayọde Alabi, igbakeji gomina to ṣoju ọga rẹ lakooko to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe ojuṣe gbogbo araalu ni ọrọ eto aabo jẹ, paapaa lakooko ipenija ti a wa lorilẹ-ede yii.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:
"Ẹ ma ṣe gbagbe lati maa ta awọn ileeṣẹ eleto aabo, awọn olori agbegbe atawọn tọrọ ba kan lolobo, nigba ti ẹ ba ri ohun ajoji tabi eeyan ti ẹ ko mọ lagbegbe yin. Bi ẹ ba ri ohunkohun, ẹ sọrọ sita lakooko to yẹ. Nipa eyi, a le daabo bo orilẹ-ede ati agbegbe wa."
No comments:
Post a Comment