Ó tún ṣẹlẹ̀ o! Wọ́n ti jí olùkọ́ fásitì gbé l'Òndó, mílíọ̀nù mẹwàá náírà ni wọ́n bèèrè - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 4, 2021

Ó tún ṣẹlẹ̀ o! Wọ́n ti jí olùkọ́ fásitì gbé l'Òndó, mílíọ̀nù mẹwàá náírà ni wọ́n bèèrè


Iroyin to tun ṣẹṣe tẹ AWIKONKO lọwọ bayii ni pe awọn agbebọn kan ti ji olukọ ile-ẹkọ fasiti ti Adekunle Ajasin to wa ni Akungba-Akoko, nipinlẹ Ondo gbe salọ.
 
Ọjọ Ẹti, Furaidee la gbọ pe wọn ji olukọ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Mayọwa Adinlẹwa, ti ẹka ikẹkọọ imọ ẹkọ, iyẹn Education gbe salọ.
 
AWIKONKO gbọ pe opopona marosẹ Akurẹ si Ado-Ekiti ni wọn ti ji Mayọwa gbe lakooko to n lọ ṣabẹwo sawọn mọlẹbi rẹ niluu Ikẹrẹ Ekiti.
 
Wọn nibi ti ọna ko ti dara lawọn agbebọn naa ti dena dee, ti wọn si yọ ibọn sii.
 
Miliọnu mẹwaa naira la gbọ pe awọn ajinigbe naa n beere bayii ki wọn to le fi Mayọwa silẹ, iyẹn gẹgẹ bi aburo rẹ, Toyin ṣe ṣalaye fun wa.
 
Funmilayọ Ọdunlami, to jẹ agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa ti sọ pe iwadii awọn ti bẹrẹ lati ri ọkunrin naa gba pada jade kuro lọwọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI