Ó parí! Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fẹ̀hónúhàn n'Ílọrin, wọ́n láwọn kò fẹ́ ìjọba Sàràkí mọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 1, 2021

Ó parí! Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fẹ̀hónúhàn n'Ílọrin, wọ́n láwọn kò fẹ́ ìjọba Sàràkí mọ́


Lonii, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, ọdun 2021, ti gbogbo awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria n ṣajọyọ ayajọ ọjọ ti wọn gba ominira kuro lọwọ iṣakoso amunilẹru, ni wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti inu n bi kan ti dide lati ṣe iwọde ifẹhonuhan lodi si iṣakoso Buọla Saraki, aarẹ ilẹ igbimọ aṣofn agba ana.
 
Ilu Ilọrin, to jẹ olu-ilu ipinlẹ Kwara la gbọ pe wọn ti ṣe ifẹhonu han naa lati tako bi wọn ṣe sọ pe Bukọla Saraki sọ ẹgbẹ oṣelu PDP di ohun ini mọlẹbi rẹ, ti ko si fẹẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ lọrọ sọ.
 
Gbogbo awọn olufẹhonu han lati wọọdun to din diẹ nigba, 193 wards to wa kaakiri ipinlẹ naa labẹ agboorun ẹgbẹ ti wọn pe ni PDP Redemption Group ni wọn lawọn ko le gba ki Saraki tubọ maa jẹ gaba le awọn lori, ati pe ohun awọn naa gbọdọ yọ ninu ẹgbẹ.
 
Bẹẹ ni wọn sọ pe awọn ko le gba ki ẹgbẹ naa bu ọwọ lu esi ipade gbogboogbo ti igun Saraki, nitori pe awọn lawọn kọkọ ṣee.
 
Ninu awọn iwe ifẹhonuhan ti wọn n gbe dani, nibi ti wọn tikọ oriṣiriṣi sibẹ pe awọn ko fẹ Saraki la tun ti gbọ pe wọn n pariwo pe awọn ko jẹ ijẹgaba Saraki mọ, iyẹn “No to Saraki dominance”.

Lakooko ti wọn n bawọn akọroyin sọrọ nibi ipade awọn oniroyin ti wọn pe, wọn sọ pe gbogbo awọn igbesẹ ti Saraki gbe lo ṣakoba fun wọn, to si jẹ pe oju ọgbẹ naa lawọn ṣi n bojuto titi dasiko yii.
 
Bakan naa ni wọn tun n rawọ ẹbẹ sawọn agbaagba ẹgbẹ naa l'Abuja lati ma ṣe ojusaaju nipa fifi fontẹ lu ipade gbogboogbo ti igun Saraki ṣe, eyi ti wọn lo tun le ṣakoba ọjọ iwaju fun ẹgbẹ PDP.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI