Ọrọ buruku toun tẹrin nigba ti baale ile, ẹni ọdun mejilelogoji kan, Jacob Joel, ẹni ti wọn fẹsun kan wi pe o fipa ko ibasun fọmọ ọrẹ rẹ, ọmọ ọdun mejila sọ pe iṣẹ eṣu ni, ati pe o jọ pe aye lo n ṣe oun.
AWIKONKO gbọ pe kii ṣe akọkọ ree ti Jacob yoo maa fipa ko ibasun fọmọ naa, to si maa n dunkooko mọ ọn wi pe ko gbọdọ tu aṣiri naa fẹnikẹni, bi ko ba fẹ koun pa a danu.
Lọjọ ti wọn sọ pe Jacob maa kọkọ ba ọmọ naa laṣepọ, ṣe lo lọ sile Jacob lati lọ ki ọrẹ rẹ, to jẹ ọmọ ọkunrin buruku yii. Wọn lọmọ naa ko ba ẹni to wa lọ, ṣugbọn to jẹ pe baba rẹ, iyẹn Jacob nikan lo wa nile.
A gbọ pe bo ṣe fẹ maa pada lọ, ni Jacob fa ọbẹ yọ wi pe ko bọ pata rẹ, to si fipa ko ibasun fun un karakara. Lẹyin eyi lo tun pada fipa ba ọmọ naa sun, koda, ti wọn ni ṣe lo sọ ọ di iṣẹ ojoojumọ.
Nigba ti aṣiri maa pada tu sita, a gbọ pe ṣe ni Jacob tan ọmọ naa lọ sinu igbo, nibi to tun ti lọ fipa ba a laṣepọ. Nibẹ si ni ọwọ palaba rẹ ti segi, to si n bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ nitori pe iṣẹ eṣu ni.
Agbẹjọro ọlọpaa, Arabinrin L. P. Fombot to foju Jacob ba ile-ẹjọ giga tilu Jos, ipinlẹ Plateau sọ pe ọpọ igba lọkunrin naa ti dunkooko mọ ọmọ yii lati fipa ba a laṣepọ, to si lo di dandan ko jiya ẹṣẹ rẹ labẹ ofin.
Agbẹjọro ọlọpaa, Arabinrin L. P. Fombot to foju Jacob ba ile-ẹjọ giga tilu Jos, ipinlẹ Plateau sọ pe ọpọ igba lọkunrin naa ti dunkooko mọ ọmọ yii lati fipa ba a laṣepọ, to si lo di dandan ko jiya ẹṣẹ rẹ labẹ ofin.
Ile-ẹjọ naa ni Jacob ti sọ pe oun ko jẹbi, nitori pe iṣẹ eṣu ni, to si n bẹbẹ fun idariji.
Onidajọ S. P. Gang ti wa paṣẹ pe ki wọn ṣi lọ fi Jacob pamọ sọgba ẹwọn titi di ọjọo keje, oṣu kejila, ọdun yii ti igbẹjọ yoo tun waye.
No comments:
Post a Comment