Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti fidi rẹ mulẹ wi pe lotitọ ni wi pe awọn agbebọn ti ji awọn ibeji Ọwalobbo tilu Obbo Aiyegunlẹ to wa nijọba ibilẹ Guusu Kwara, Ọwa Samuel Olulẹyẹ Adelodun; awakọ kabiyesi ti wọn pe ni Kunle; ẹṣọ aabo ti wọn pe ni Lawrence Abiọdun ati ọmọ-ọdọ, iyẹn Bukunmi Akanbi gbe salọ.
Ọjọ Ẹti, Furaide to kọja yii ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe olobo ti ta awọn i pe wọn ti ji awọn eeyan naa gbe, ti wọn si ni ọmọ ọdun mẹfa lawọn ibeji Kabiyesi ti wọn ji gbe salọ yii.
Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara jẹ ko di mimọ pe nnkan bi aago mẹfa aabọ, Ọjọbọ, Tọside ni iṣẹlẹ yii waye. O sọ pe inu mọto Toyota Sienna to jẹ ti kabiyesi lawọn maraarun wa nigba tawọn agbebọn naa da wọn lọna.
A gbọ pe bi wọn ṣe ji awọn eeyan naa gbe, ni wọn ti fi mọto wọn silẹ loju ọna.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati ri awọn eeyan naa gba kuro lọwọ awọn ajinigbe, ti wọn si n rawọ ẹbẹ sawọn araalu lati jẹ ki wọn mọ, iyẹn bi wọn ba ri ipasẹ awọn oniṣẹ ibi lagbegbe wọn.
No comments:
Post a Comment