'Iru kileyi' ni ariwo ti pupọ awọn to wa nile-ẹjọ Majisireeti tilu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun mu sẹnu, nigba ti Onidajọ Abiọna Adebayọ ju iya ati ọmọ rẹ kan sẹwọn ọdun mẹrin gbako pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun wi pe wọn ji miliki ati siga gbe.
Iya naa, Arabinrin Bọlaji Ẹlẹṣhọ, ẹni ogoji ọdun ati ọmọ rẹ, Bidemi toun jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelogun ni ile-ẹjọ naa ko sọ pe ki wọn lọ fi ẹwọn ọdun mẹrin naa gbara.
AWIKONKO gbọ pe ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹsan to kọja yii ni Bidemi ati mama rẹ, Bọlaji jale naa ladugbo Ararọmi, to wa loju ọna Owode Ileṣa si Ọba-Ọba nilu Oṣogbo.
Wọn ni ṣọọbu obinrin kan to n jẹ Nafisat Adeyẹye lawọn mejeeji lọ ja ni nnkan bi aago mẹrin aabọ oru, nibi ti wọn ti ji paali siga mẹrin ti owo rẹ ko din ni ẹgbẹrun mẹrindinlogun naira; paali siga Bohem meji ti owo rẹ ko din ni ẹgbẹrun mẹjọ naira, paali siga Rezler meji ati paali miliki meji ti owo wọn ko din ni ẹgbẹrun mẹrindinlọgbọn naira gbe.
Yatọ si awọn nnkan wọnyi, a gbọ pe wọn tun ji ọsẹ ifọnu (toothpaste), ohun mimu ẹlẹrin dodo ti Yoghurt meji, ati awọn ẹru mi-in ti owo wọn ko din lẹgbẹrun mọkanlelaadọjọ, (N151, 000) naira gbe.
Oju ọna, lakooko ti wọn n ji awọn ọja naa gbe salọ lọwọ awọn ọlọdẹ tẹ wọn, ti wọn si lọ fa wọn le awọn ọlọpaa lọwọ.
Gbogbo ẹsun yii ni wọn lo tako iwe ofin ọdaran ti abala 516, 413, 390 (9) ati 430 tipinlẹ Ọṣun, iyẹn tọdun 2002.
Nigba to n gbe idajọ naa kalẹ lori ẹsun mẹrin ọtọọtọ ti wọn fi kan wọn, Onidajọ Adebayọ sọ pe ki awọn mejeeji lọ fi ẹwọn ọdun mẹrin gbara.
Onidajọ Adebayọ sọ pe anfaani wa fun Bọlaji lati san ẹgbẹrun mẹẹdogun naira gẹgẹ bi owo itanran, iyẹn bi ko ba fẹẹ ṣẹwọn; bẹẹ lo ni ki ọmọ rẹ, Bidemi san owo itanran, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira boun naa ko ba fẹẹ ṣẹwọn.
No comments:
Post a Comment