Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Borno, to wa nilu Maiduguri ti ju iyaale ile kan, Dije Sale sẹwọn ọdun mẹrinlelọgbọn nitori ẹsun jibiti ati yiyi iwe ti wọn fi kan an, eyi ti wọn lo fi ji owo ti ko din ni miliọnu mẹrindinlaadọrin (N66m) naira gbe salọ.
Onidajọ Umaru Fadawu lo gbe idajọ naa kalẹ, lori ẹsun ti ajọ Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), to n gbogun ti iwa jibiti lorilẹ-ede yii fi kan an.
AWIKONKO gbọ pe ọjọ kin-in-ni, oṣi keje, ọdun to kọja, iyẹn 2020 ni wọn kọkọ foju rẹ ba ile-ẹjọ, lori ẹsun mẹta ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu jibiti.
Wọn ni ṣe ni Sale gbe ayederu iwe kan jade, lati fi gbe iṣẹ jade fun ileeṣẹ kan.
Onidajọ Fadawu ju Sale sẹwọn ọdun mẹrinla lori ẹsun kin-in-ni; ẹwọn ọdun mẹwaa lori ẹsun keji, ati ẹwọn ọdun mẹwaa lori ẹsun kẹta. Bẹẹ lo tun paṣẹ wi pe ko da miliọnu mẹrinlelaadọta naira pada fun awọn to lu ni jibiti naa.
No comments:
Post a Comment