Aṣeyọri to lọọrin nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tun ṣe lọjọ Aiku, Sannde ana, nigba ti wọn rọwọ to awọn ajinigbe meji kan lakooko ti wọn fẹẹ gba owo abẹtẹlẹ lọwọ mọlẹbi ẹni ti wọn jigbe.
Muhammed Abubakar, ẹni ọdun mejilelogoji ati Clinton Niche toun jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun lọwọ palaba wọn segi ninu igbo kijikiji kan to wa nilu Agbara, ipinlẹ naa.
AWIKONKO gbọ pe, ọmọ ọdun meje kan, Daniel Ajibili lawọn mejeeji yii jigbe, ti wọn si n beere ransọṣomu lọwọ baba rẹ, Stephen Ajibili.
Owo ti wọn n beere naa lọ jẹ ko gba teṣan ọlọpaa Agbara lọ lati fi to wọn leti. Stephen sọ pe iyawo oun, to jẹ iya ọmọ naa lo ran an niṣẹ laago mọkanla kọja oju iṣẹju. Oju ọna lọmọ naa wa, ti wọn fi jiigbe, to si ni miliọnu kan naira ni wọn n beere lọwọ oun lati fi gba ọmọ oun silẹ.
Bawọn ọlọpaa ṣe gbọ, ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii, ti wọn si ni ki awọn obi ọmọ yii ṣe ohun tawọn ajinigbe naa n fẹ. Nibi ti wọn ti fẹẹ gba owo naa lawọn ọlọpaa ti raga bo wọn, ti wọn si ko awọn mejeeji.
Awọn mejeeji ni wọn pada mu awọn ọlọpaa lọ sibi ti wọn de ọmọ naa mọ. Nibẹ ni wọn si ti ṣakiyesi pe mẹta lawọn ajinigbe naa, ṣugbọn ti ẹnikan yooku wọn ti na papa bora, ni kete to ti gbọ pe awọn ọlọpaa ti wa nitosi.
Nigba to n sọrọ, adele kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abiọdun Alamutu, ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn meji naa lọ si ẹka ileeṣẹ wọn, to n ri sọrọ ijinigbe lati tubọ ṣe iwadii wọn, ko to di pe wọn foju ba ile-ẹjọ, to si ni wọn gbọdọ rọwọ to ẹnikan yooku toun na papa bora.
No comments:
Post a Comment