Ní Ṣagamu: Bàbá arúgbó kú sórí aláṣẹ́wó lásìkò ìbálòpọ̀ gbígbóná l'òtẹ́ẹ̀lì, wọ́n ní kìí ṣojú lásán - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 15, 2021

Ní Ṣagamu: Bàbá arúgbó kú sórí aláṣẹ́wó lásìkò ìbálòpọ̀ gbígbóná l'òtẹ́ẹ̀lì, wọ́n ní kìí ṣojú lásán


Kayeefi nla gba a lọrọ baba arugbo, ẹni ọdun mọkanlelaadọrin kan, Ajibọla Olufẹmi Adeniyi, ṣi n jẹ fun ọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, paapaa awọn olugbe ipinlẹ Ogun lori bi wọn ṣe sọ pe baba naa ku sori alaṣẹwo lotẹẹli kan to wa nilu Ogijo, ijoba ibilẹ Ṣagamu.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni otẹẹli kan ti wọn n pe ni 50/50 ni baba yii ku si lọjọ Aje, Mọnde to kọja yii.
 
A gbọ pe ojule kejileloogun, adugbo Akilọ to wa ni Bariga, ipinlẹ Eko ni Ajibọla n gbe, ibẹ si ni wọn lo ti lọ si otẹẹli naa lati lọ ṣe faaji ara rẹ.
 
Wọn ni bi Ajibọla ṣe de otẹẹli naa lo ti sọ pe ki wọn ba oun wa alaṣẹwo kan ti yoo ṣe gbogbo ere foun tilẹ ọjọ keji yoo fi mọ, eyi lo jẹ ki wọn lọ pe Joy, ẹni ti wọn sọ pe ko niṣẹ meji ju iṣẹ aṣẹwo lọ.
 
AWIKONKO gbọ pe nibi ti Ajibọla ti n ko ibasun fun Joy, alaṣẹwo naa lọwọ ni ọrọ ti béyin yọ, ti wọn si ni baba naa gbabẹ sọda sọrun alakeji.
 
Wọn lariwo ti Joy pa pe kawọn gba oun lo mu kawọn to wa nibẹ sare wọle, ti wọn si ba Ajibọla nilẹ. Ki oloju to o ṣẹ ẹ, wọn ni baba naa ti ta teru nipa.
 
Loju ẹsẹ ni wọn ti ranṣẹ ọlọpaa, ti wọn si gbe oku Ajibọla lọ mọṣuari ọsibitu ijọba to wa nilu Ṣagamu, bẹẹ ni wọn mu Joy gba teṣan wọn lati lọ fọrọ wa a lẹnu wo nipa iru iku to ba baba yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI