Lọjọ Aje, Mọnde, ana, ọjọ kejidinlogun ni gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq kede Amofin Sambo Murtala, gẹgẹ bi oludamọran pataki lori ọrọ to nii ṣe pẹlu ofin (Special Adviser on Legal Matters).
Gbajugbaja ajafẹtọ-ọmọniyan ni Murtala nipinlẹ Kwara, to si ti ko ipa rere, eyi to ṣee fi yangan lawujọ laari awọn araalu.
Ẹkọ nipa ofin ni Murtala kọ nipa rẹ nilẹ-ẹkọ fasiti tiluu Ilọrin laaarin ọdun 2005 si ọdun 2010, ko to di pe o tẹsiwaju nile-ẹkọ awọn amofin ti orilẹ-ede Naijiria, nibi to ti kẹkọọ gboye LLB lọdun 2011.
Yatọ si eyi, Murtala tun kẹkọọ siwaju sii nile-ẹkọ musulumi to n ri sọrọ ofin, iyẹn College of Arabic and Islamic Legal Studies, nibi to ti gba oye Diploma in Common and Islamic Law.
Iyẹn nikan tun kọ, Murtala wa lara igbimọ Kwara State Transition Committee lọdun 2019, bẹẹ lo tun jẹ igi lẹyin ọgba fun Kwara Development Trackers, to si tun jẹ akọwe fun ẹgbẹ awọn alẹnulọrọ nilu Ilọrin, iyẹn Ilorin Emirate Stakeholders Forum.
No comments:
Post a Comment