Ọwọ ileeṣẹ Sifu Difẹnsi nipinlẹ Ondo ti tẹ awọn afurasi adigunjale mẹta yii, Gospel Oṣuọla, ọmọ ọdun mẹrindinọgbọn; Ọladele Ibukun, ọmọ ọdun mejilelogoji ati Dayọ Akinlafẹ, toun jẹ ẹni ogoji ọdun.
AWIKONKO gbọ pe ko din ni ẹrọ to n ṣe onka ina mọnamọna, iyẹn Prepaid Meter mẹjọ ti awọn mẹtẹẹta jigbe lagbegbe Alagbaka to wa ni Ijapo Estate nilu Akurẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu to kọja yii.
Ileeṣẹ Sifu Difẹnsi sọ pe awọn mẹtẹẹta jẹwọ funra wọn nigba tọwọ tẹ wọn, koda, ti wọn sọ pe awọn ni wọn ṣalaye bi wọn ṣe ji awọn mita naa gbe salọ.
Wọn jẹ ko ye wa pe awọn eeyan naa sọ pe ẹgbẹrun lọna ọgọta, ₦60,000 naira lawọn maa n ta awọn mita naa fawọn onibara wọn, eyi ti wọn lo tako ofin aṣemaṣẹ ti ọdun 2004.
Ọga agba pata fun ileeṣẹ naa, Hammẹd Abọdunrin sọ pe iṣẹ ofintoto ati ọtẹlẹmuyẹ tawọn ṣe lo tu aṣiri awọn mẹtẹẹta si wọn lọwọ, to si ni wọn yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ.
No comments:
Post a Comment