Mi ò ṣẹ̀ṣẹ̀ maa fi orí òkú ṣètùtù fáwọn ọmọ Yahoo - Ismaila jẹ́wọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 31, 2021

Mi ò ṣẹ̀ṣẹ̀ maa fi orí òkú ṣètùtù fáwọn ọmọ Yahoo - Ismaila jẹ́wọ́


Ismaila Wasiu, ọkan lara awọn ọkunrin meji ti wọn ka ori oku ati awọn ẹya ara oku mọ lọwọ laipẹ yii nilu Ṣaki, Oke-Ogun nipinlẹ Ọyọ ti pada jẹwọ sita wi pe kii ṣe akọkọ ree toun yoo ma fi ori ati ẹya oku ṣetutu aje fawọn ọmọ Yahoo.
 
Lakooko to n jẹwọ naa lo sọ pe ori gbigbẹ loun maa n lọ ra tẹlẹ lati maa fi ṣetutu, ko di pe oun tun dagbasoke lati maa lo ori tutu ai ẹya ara tutu, eyi ti yoo mu iṣẹ ya fun etutu aje ati ọla.
 
Siwaju sii lo sọ pe oun loun tan ọrẹbinrin oun to n jẹ Mujidat, lati ilu Eko wa si ilu Ṣaki, pẹlu erongba lati lo ori rẹ ati ẹya ara rẹ fi ṣe etutu owo fawọn ọmọ Yahoo, eyi ti yoo mu iṣẹ ya ju ti tẹlẹ lọ.
 
Wasiu, ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn ati ọrẹ rẹ tọwọ jọ tẹ lakooko kan naa, Mutairu Shittu, ẹni ọdun marundinlogoji lọwọ palaba wọn segi ni nnkan bi aago meji aabọ, ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii.
 
A gbọ pe awọn ara agbegbe Ayekale to wa nilu Ṣaki ni wọn ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo wi pe awọn kofiri awọn kan pẹlu ori ati ẹya ara oku, ti wọn si lawọn ọlọpaa sare lọ sibẹ lati lọ mọ otitọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI