Ọmọ ogun ọdun kan, Ayọ Adenupebi ti jẹwọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Eko wi pe loootọ loun fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹsan kan, ati pe iṣẹ eṣu ni, nitori pe oun ko mọ pe aṣiri maa pada tu.
Ilu Ise to ni Akodo niṣẹlẹ naa ti waye nipinlẹ Eko, gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Adekunle Ajiṣebutu ṣe ṣalaye f'AWIKONKO.
Ajiṣebutu sọ pe ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa ti a wa yii ni ẹgbọn ọmọ naa wa fi ẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa wi pe Ayọ fipa ja ibale aburo oun, ati pe awọn ri ẹjẹ rẹpẹtẹ lara aṣọ rẹ, eyi to fidi rẹ mulẹ.
O loju ẹsẹ lawọn ọlọpaa ti lọ gbe e, to si jẹwọ pe lotitọ ni, ati pe iṣẹ eṣu ni.
Ajiṣebutu sọ pe ọga awọn, Hakeem Odumosu ti paṣẹ pe ki iwadii tubọ bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.
No comments:
Post a Comment