Lẹyin ipade gbogboogbo wọọdu ti wọn ṣe, alaga meji-meji lẹgbẹ oṣelu PDP ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 3, 2021

Lẹyin ipade gbogboogbo wọọdu ti wọn ṣe, alaga meji-meji lẹgbẹ oṣelu PDP ni Kwara


Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe yoo tun ṣoro gidigidi fẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), lati pada ri ọwọ mu lorilẹ-ede yii.
 
A gbọ pe alaga meji-meji lo ti dide bayii lẹyin ipade gbogboogbo tẹgbẹ oṣelu PDP ṣe kaakiri wọọdu to wa nipinlẹ naa.
 
Bawọn ọmọ naa ti wọn jẹ ọmọ ẹyin Bukọla Saraki, aarẹ ile igbimọ aṣofin agba orilẹ-ede yii tẹlẹri ṣe yan awọn alaga ti wọn, bẹẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn pe ara wọn ni PDP Redemption Group yan awọn alaga ti wọn ninu ipade gbogboogbo miran.

Nigba to n sọrọ lorukọ PDP Redemption Group, Lawal Nurain to jẹ agbẹnusọ wọn sọ pe ẹgbẹ naa ko pin si meji, nitori pe awọn oloye ti wọn yan ninu igun naa ni ojulowo.
 
O sọ pe ẹnikẹni to ba n pe ara rẹ ni alaga, tabi oloye ẹgbẹ ni wọọdu kan n tan ara wọn lasan ni, nitori pe awọn gan-an ni wọn n da ẹgbẹ naa ru.
 
Gbogbo akitiyan lati ba Ọnarebu Kọla Shittu to jẹ agbẹnusọ ẹgbẹ PDP nipinlẹ naa sọrọ lo ja si pabo titi dasiko taa ṣakojọpọ iroyin yii tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI