Iṣẹ́ ajínigbé làwọn eléyìí n ṣe jẹun kí ọwọ́ tóó tẹ̀ wọ́n - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 17, 2021

Iṣẹ́ ajínigbé làwọn eléyìí n ṣe jẹun kí ọwọ́ tóó tẹ̀ wọ́n


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti tẹ awọn mẹta kan,
Salihu Usman, Mubarak Aliyu ati Sahibul Husna Auwal ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ ajinigbe lọ, ti wọn si ti wa nibi ti wọn ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo lọwọ.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ọjọ Ẹti, Furaide, ana lọwọ tẹ awọn mẹtẹẹta lagbegbe kan ti wọn n pe ni Sharada quarters, eyi to wa nilu Kano, ipinlẹ Kano. 
 
Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Abdullahi Haruna Kiyawa to fi iroyin ọhun to wa leti lonii, ọjọ Abamẹta, Satide jẹ ko di mimọ pe ọkan lara awọn ara agbegbe Kwanar Ganduje, Sharada Phase II Quarters, lo ta wọn lolobo loṣu to kọja, ti iwadii si bẹrẹ.
 
Kiyawa sọ pe ẹni naa loun gba ipe wi pe koun san miliọnu meji naira, bi ko ba fẹ kawọn ji oun tabi mọlẹbi rẹ yoowu gbe.
 
O ni lẹyin tawọn gba olobo naa, ni ọga awọn, Sama’ila Shu’aibu Dikko, gbe igbimo ọtẹlẹmuyẹ dide, ti ọwọ si pada tẹ awọn mẹtẹẹta yii.
 
Nigba tọwọ tẹ wọn, gbogbo wọn jẹwọ e lotitọ lawọn dunkooko mọ ẹni naa wi pe awọn yoo gba miliọnu meji naira lọwọ ẹ, bi ko ba fẹ kawọn ji oun tabi eyikeyi mọlẹbi rẹ gbe.
 
Bakan naa ni wọn tun jẹwọ pe awọn ti kọkọ gba miliọnu kan naira lọwọ ẹ tẹlẹ.
 
Ileeṣẹ ọlọpaa ti wa jẹ ko di mimọ pe awọn mẹtẹẹta wọnyi yoo foju ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI