Ìjọba Kwara fi ìtàn tuntun balẹ̀, wọ́n dá ilé-ẹ̀kọ́ girama tàwọn ọlọ́pàá sílẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 8, 2021

Ìjọba Kwara fi ìtàn tuntun balẹ̀, wọ́n dá ilé-ẹ̀kọ́ girama tàwọn ọlọ́pàá sílẹ̀


Lojuna lati jẹ ki awọn ọmọde mọ pataki iṣẹ eto aabo, lati mọ ọna ti wọn le gba lati maa ṣiṣẹ ojulalakanfinṣọri, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman Abdulrazaq ti fitan tuntun balẹ nipa dida ile-ẹkọ girama, nibi ti wọn yoo ti maa kọ ẹkọ nipa iṣẹ ọlọpaa silẹ.
 
Ile-ẹkọ naa ni wọn pe ni Police Secondary School, agbegbe Ballah, ipinlẹ Kwara lo wa, ninu ọgba ile-ẹkọ Government Day Secondary school (GDSS) tẹlẹri.
 
Nigba to n ṣabẹwo sinu ọgba ile ẹkọ naa ti wọn n ṣe lọwọ, Kọmiṣanna fọọ eto ẹkọ, Hajiya Sa'adatu Modibbo Kawu, sọ pe iṣẹ ti lọ gidi gan-an, to si ku diẹ ko pari, ki ile-ẹkọ naa le bẹrẹ ni pẹrẹu.
 
Kawu sọ pe lara awọn ileri lati jẹ ki eto aabo tubọ fẹsẹ rinlẹ daadaa, ati ọna ti ijọba gba mu ọrọ eto ẹkọ lokunkundun lo jẹ ki wọn gbe igbesẹ lati yọri rẹ.
 
AWIKONKO gbọ pe ọdun 2017 lo yẹ ki wọn ti bẹrẹ ile-ẹkọ naa, ṣugbọn ti ijọba igba naa ko ṣe ojuṣe wọn, ti ijọba yii si ri gẹgẹ bi ojuṣe lati ṣe.
 
Egbẹ kan ti wọn pe ni Ilorin Emirates Development Progressive Union, iyẹn IEDPU la gbọ pe wọn gbe erongba yii kalẹ.
 
Awọn olukọ ati akẹkọọ la gbọ pe wọn ti bẹrẹ iṣẹ lakọtun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI