Boroboro bayii ni gendekunrin kan ti won pe ni Ridwan Kasali n ka nigba tọwọ ẹṣọ alaabo ilẹ Yoruba, iyẹn Amọtẹkun tẹ ẹ lakooko to n ji ọmọ kekere kan gbe nilu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun.
A gbọ pe bi ọwọ ṣe tẹ Kasali, lo ti bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ, ati pe oun ti wa nidi iṣẹ naa tipẹ.
Adugbo Yẹmẹtu Secretariat to wa nilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ la gbọ pe Kasali ti maa lọ kaakiri lati lọ ji awọn eeyan gbe, ti yoo si lọ ta wọn danu sipinlẹ Eko ati Ibadan.
Kasali nigba to n jẹwọ sọ pe eeyan ti ko din ni marun-un ọtọọtọ loun ti jigbe, toun si ti ta wọn danu fun ẹnikan to pe ni Abija.
Nigba to n sọrọ, ọga agba Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Kọmureedi Amitolu Shittu sọ pe awọn ti fa Kasali le awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọwọ lati tubọ ṣe iwadii rẹ siwaju sii.
Bẹẹ lo sọ pe Kasali tun jẹwọ pe gbogbo awọn maraarun toun jigbe ni wọn ti pa danu.
No comments:
Post a Comment