Ọwọ ileeṣẹ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ẹka tilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ ti tẹ awọn mẹrindinlọgbọn kan ti igbagbọ wa wi pe wọn lọwọ si iwa jibiti ori ayelujara ti ọpọ awọn eeyan mọ si Yahoo-Yahoo.
Lara awọn mẹrindinlọgbọn yii la gbọ pe awọn gbajugbaja babalawo meji ti wọn n ṣiṣẹ fun wọn naa wa.
Gẹgẹ bi Ọgbẹni Wilson Uwujaren, to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ EFCC ṣe ṣalaye lọjọ Ẹti, Furaide ana, o ni agbegbe Soka nilu Ibadan lọwọ ti tẹ pupọ ninu wọn.
O ni agbegbe Soka ọhun lọwọ ti tẹ awọn babalawo meji naa pẹlu awọn mẹrinlelogun miran, eyi ti meji ninu wọn jẹ akẹkọọ fasiti Lead City.
Uwujaren sọ pe bo tilẹ jẹ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ, sibẹ, o ni pupọ wọn lo ti n jẹwọ fawọn wi pe iṣẹ naa lawọn fi n gbọ bukata aye wọn.
Bẹẹ lo tun sọ pe mọto bọginni loriṣiriṣi, foonu olowo nla loriṣiriṣi, tẹlifiṣan, kọmputa alegbeeka ati geemu, atawọn nnkan miran ni wọn gba lọwọ wọn.
No comments:
Post a Comment