Gbajúmọ̀ Àláájì tó fi dúkìá oní dúkìá lu jìbìtì ọgbọ̀n mílíọ̀nù náírà l'Abuja ti dèrò ọgbà ẹ̀wọ̀n Kùjé o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 19, 2021

Gbajúmọ̀ Àláájì tó fi dúkìá oní dúkìá lu jìbìtì ọgbọ̀n mílíọ̀nù náírà l'Abuja ti dèrò ọgbà ẹ̀wọ̀n Kùjé o


Ile-ẹjọ giga to wa lagbegbe Wuse, Federal Capital Territory l'Abuja ti sọ pe ki ileeṣẹ to n ri sọrọ iwa jibiti ati ajẹbanu lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) lọ fi Alaaji Haruna Husseini pamọ sọgba ẹwọn Kuje titi di ọjọ keji, oṣu kọkanla ọdun yii ti igbẹjọ yoo tun pada waye.
 
Ẹsun meji ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu iwa jibiti, iyẹn gbajuẹ ati ẹtanjẹ la gbọ pe wọn fi kan gbajugbaja Alaaji Haruna yii, niwaju Onidajọ A. S. Adepọju.
 
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni Alaaji Haruna fi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹni to ni dukia kan to wa ni Plot No. 167 Katempe District niluu Abuja, to si luu ta ni gbajo fun ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Vincent Mshelia ninu oṣu kọkanla, ọdun 2013.
 
Ọgbọn miliọnu naira la gbọ pe Alaaji Haruna ta dukia ọhun, eyi ti wọn lo lodi sofin iwa jibiti.
 
Iwe 'emi ni mo nilẹ' ti wọn n pe ni Certificate of Occupancy to jẹ ti dukia naa, eyi ti Ibrahim Baba Chaichai gbe lee lọwọ lo fi lu jibiti naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
AWIKONKO gbọ pe nigba ti wọn ka ẹsun yii si Alaaji Haruna leti, ṣe lo sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, eyi to mu ki agbẹjọro rẹ, Nkechukwu Odanwu bẹbẹ pe ki wọn gba beeli ẹ, ko le maa gba ile wa sile ẹjọ, ati pe nitori ailera rẹ.
 
Onidajọ Adepọju wa paṣẹ pe ko tii saaye fun beeli, bi ko ṣe pe ki ajọ EFCC lọ fi ọkunrin naa pamọ titi digba ti igbẹjọ yoo tun pada waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI