Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Peter Ayọdele Fayoṣe ti ṣe abẹwo si Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmẹd Tinubu lonii, ọjọ kejila, oṣu kẹwaa, ọdun 2021 nile rẹ to wa ni Ikoyi, ipinlẹ Eko.
Nibẹ lo ti sọ pe aisan ko mọ ẹgbẹ oṣelu, ati pe oun ko si lara awọn to maa n lọ lati lọ tọwọ bọwe ibanikẹdun, ati pe oun wa lara awọn to maa n bu ọla fun awọn to ba tọ si.
Bẹ o ba gbagbe, o ti pẹ ti Fayoṣe, ẹni to jẹ agba ati alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP lorilẹ-ede Naijiria ti n sọ pe oun yoo wa ọjọ kan pato lati ṣe abẹwo si Aṣiwaju Tinubu.
Fayoṣe ninu awọn ọrọ rẹ maa n sọ pe oun kii ṣe oloṣelu ti kii gba ifẹ ati iṣọkan laaye, bi ko ṣe ẹni to n wa ilọsiwaju ilu, paapaa ilẹ Yoruba.
Nigba to n sọrọ lẹyin abẹwo ọhun, o sọ ninu ọrọ rẹ pe:
"Lonii, mo wa ni Bourdillon, Ikoyi, l'Ekoo lati ki Aṣiwaju Ahmẹd Bọla Tinubu fun ti ailera rẹ, ti mo si gbadura pe kai ara rẹ tete ya.
"Ọrọ ilera ko mọ ẹgbẹ oṣelu kankan, ati pe ninu aye yii, kii wọpọ lati maa mọ riri awọn eeyan nigba ti wọn ba wa laye. Eyi to pọ ju ni pe ka lọ maa tọwọ bọ iwe ibanikẹdun. Ni temi o, kii ṣe ohun to dara rara.
"Eyi to ja ju ni pe, oṣelu gbọdọ jẹ nipa ifẹ ti a n ni si ara wa. Fun idi eyi, gẹgẹ bi awọn agba miran lorilẹ-ede Naijiria, mo n ki Aṣiwaju pe ki ara rẹ tete ya kiakia.
"Ati si awọn ti kii ri nnkan gidi nipa oṣelu, abẹwo mi yii ko ni nnkan ṣe. Mo ṣi jẹ aṣiwaju ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ti mi o si le kiro nibẹ lailai."
No comments:
Post a Comment