Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede sita wi pe eto ẹyawo onirọrun ti bẹrẹ fun gbogbo awọn ileeṣẹ ati olokoowo kekeekee kaakiri ipinlẹ naa, lojuna lati jẹ ki eto ọrọ aje tubọ dagbasoke kọja afẹnusọ.
Ọjọru, Wẹside, ijẹta ni iforukọsilẹ naa bẹrẹ fun gbogbo ileeṣẹ kereje-kereje ati olokoowo kekeekee, iyẹn MSMEs, eyi ti wọn pe ni NG-CARES.
Nipa iranlọwọ ati ajọṣepọ banki agbaye la gbọ pe ijọba Kwara fi fẹẹ ṣe iranlọwọ nla yii fun awọn araalu lati jẹ anfaani mudunmudun iṣejọba awaarawa, paapaa lati le jẹ ki nnkan pada bọ sipo latigba ti ajakalẹ arun korona ti dẹnu eto ọrọ aje kọlẹ.
Eto ẹyawo yii yoo gbe awọn ileeṣẹ naa dide pada, ti wọn yoo si tun maa ṣe daadaa ju ti tẹlẹ lọ.
Gẹgẹ bi Ọgbẹni Muhammed Brimah to jẹ alakoso ẹgbẹ to n ṣakoso eto ẹyawo yii ṣe sọ, o ni gbogbo awọn ileeṣẹ ati okoowo ti wọn ti n ṣe nipinlẹ Kwara nikan lati bi ọdun meji sẹyin ni anfaani yii wa fun.
Aago mẹwaa, ọjọ kẹfa, oṣu yii ni iforukọsilẹ bẹrẹ lori ikanni ayelujara ti https://www.kwassip.org/kwaracares, ti yoo si pari lọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, eyi tii ṣe ọsẹ meji gbako.
Lati forukọsilẹ jẹ anfaani yii, ẹ lọ si KWARA NG-CARES
No comments:
Post a Comment