Lati le ma jẹ ki awọn alagbara ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Eko, fọwọ agbara gba wọn, lori bi wọn ṣe gba fọọmu lati dije fun ti awọn ipo oloye ẹgbẹ, ṣugbọn ti wọn ko jẹ ki wọn ṣe ojuṣe wọn bi ọmọ ẹgbẹ naa. Conscience Forum naa ṣeto ibo ti wọn naa laye ọtọ.
Lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii ni Conscience Forum, eyi ti Ọnarebu Mọshood je adari wọn dibo yan Mustapha Dabiri atawọn marundinlogoji mii in gẹgẹ bi oloye fẹgbẹ oṣelu APC, ipinlẹ Eko.
Nibi ibo naa to waye ni gbọngan ayẹyẹ Irewọle, niluu Eko, lawọn ọmọ ẹgbẹ naa ti dibo yan awọn oloye tuntun ọhun.
Awọn yooku ti won tun dibo yan ni Alaaji Akeem Fagbemi (Mushin) gẹgẹ bi igbakeji alaga, nigba ti Ọnarebu Olujimi Ṣhobayọ lati Amuwo-Ọdọfin jẹ igbakeji akọwe.
Bakan naa ni wọn tun dibo yan Olukọgbọn Stephen Babatunde (Ikeja), toun jẹ igbakeji akowe; Ẹni-ọwọ Adeṣẹgun Samson, igbakeji alaga; Ọnarebu Kunle Okunọla (Ikeja), igbakeji alaga loun naa.
Bẹẹ naa ni Ọnarebu Adebọwale Adeshakin (Surulere), naa tun jẹ igbakeji alaga; Amofin Ibijọkẹ Tijani Fadugba (Ifako Ijaiye), ni oludamoran won nipa ofin; nigba ti Amofin Tunde Adelekan Ajibade, si jẹ igbakeji ẹ. Arabinrin Modupẹ Awẹ (Alimosho), ni akapo.
Nigba to n sọrọ nibi eto ibo naa, Ọnarebu Salvador, to jẹ alaga ikọ naa gba awọn olori ẹgbẹ lamọran lati ma ṣe gba igbakugba laaye.
O ni ki wọn ma ṣe nnkan to le mu wahala ba ibo ọjọ iwaju, nitori bi nnkan ṣe n lọọ yii, idaamu nla ni yoo muu wa ti agbara si le ma ka mọ.
Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ toun naa tun sọrọ lọjọ naa sọ pe inu awọn ko dun si nnkan to n waye ninu ẹgbẹ oṣelu APC, nitori bo ṣe jẹ pe oriṣiriṣi igun lo ṣe ibo lọdọ wọn ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.
O ni ohun to dara ni bi awọn oloye ẹgbẹ lapapọ ba le tete gbe igbesẹ, ki nnkan ko ma ba a bajẹ ju bayii lọ. Bakan naa ni iru ibo mii in to tun waye ni ẹgbẹ naa ni wọn ti yan.
Pasitọ Cornelius Ọjelabi, gẹgẹ bi alaga fun ti ikọ Mainstream Lagos APC, nigba tawọn ti Lagos4Lagos Movement yan Ọmọọba Sunday Ajayi, bi alaga t'ọdọ ti wọn, Beatrice Ọmọtayọ lawọn ti Akinwunmi Ambọde-led AAMCO naa yan lọdọ ti wọn.
Ni bayii alaga ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Eko, ti di mẹrin, ta a wa ni ẹru n ba bayii.
No comments:
Post a Comment