Bọ́lá Ahmẹd Tinubu nìkan ni ẹni náà tó lè ṣe Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà - Alukoro ẹgbẹ́ APC l'Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 25, 2021

Bọ́lá Ahmẹd Tinubu nìkan ni ẹni náà tó lè ṣe Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà - Alukoro ẹgbẹ́ APC l'Ékòó


Ọnarebu Ṣẹyẹ Ọladẹjọ, alukoro fẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Eko, ti sọ pe lakooko yii,  ko tii si ẹni to kun oju oṣuwọn lati di aarẹ orileede yii ninu ibo to n bọ lọdun 2023, yatọ si Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, nitori awọn iriri to ti ni lori ijọba awarawa.

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ, o sọ pe bo tilẹ jẹ pe titi di akoko yii ọkunrin naa ko tii sọ erongba ẹ sita lati fije ṣugbọn gbogbo awọn lawọn n rọ ọ lati jade nitori oun nikan ni olugbala awọn mẹkunnu ti wọn ti n reti.

O sọ pe '' Bi a ba pe ori akọni, a fi ida laalẹ, Baba wa ti ẹ darukọ yẹn, ẹni ti Ọlọrun da,ẹni ti Ọlọrun gbe kalẹ fun wa lakooko yii, lati waa ṣe atunṣe ati afọmọ awọn nnkan to ti wọ latẹyin wa. Ko to to akoko yii, oloore lo jẹ si ọpọlọpọ eeyan.

''Irufẹ ẹda to jẹ lo mu ki ọpọlọpọ awọn kan sọ pe idije aarẹ yii, awọn ṣetan lati sanjọ oore fun Baba wa Bọla Ahmed Tinubu, ẹ ẹ tun waa rii pe ohun to tun waa faa taa fi n ri ọpọ awọn eeyan kaakiri orileede yii ti wọn fi sọ pe a fi dandan ki wọn jade.

''Baba wa titi di akoko yii, ẹnikẹni ko le sọ pe, baba pe awọn lati waa gbaruku ti wọn, bi awa ọmọ ti wọn ti ṣe loore ṣe n sọrọ to. Ẹ ẹ wa ri i pe oun to tọ, to si yẹ  fun ẹnikẹni to ba nifẹẹ ilu yii, ṣe nipa iriri ni tabi nipa awọn ohun meremere to ti gbese lorileede yii tabi nipa iriri ijọba alagbada, ijọba tiwantiwa lorileede yii, a bi nipa awọn to ti tipa baba jade lati ori aarẹ, igbakeji ẹ. atawọn gomina''.

''Ohun to waa jẹ idojukọ lorileede yii lakooko yii, ṣe ọrọ aje ni, okoowo,pẹlu oye to ni, ẹni to o to gbangba sun lọyẹ ni wọn. Adura wa ni pe ninu ẹgbẹ APC, ki baba gba si wa lẹnu lati dupo aarẹ, niwọngba to jẹ pe ohun eeyan ni ohun Ọlọrun''.
 
Bẹẹ lo tun sọ pe ''Lati ọjọ ti alaye ti daye, bẹẹ ni, ọjọ ti ko ba si ni saaye mọ, wọn ni, wọn pe, ko nii kuro,ọja ti awa n ta ni a ni fi epo ati iyọ si, wọn ja nile keji, ko kan mi, bi a ba tun ni ki a daalẹ, ki a tun sa, wọn ni aifi agba fẹnikan, ko jẹ ki aye gun.

''Ẹ ẹ ma jẹ ki a tan ara wa jẹ, ika to ba tọ si imu lakooko ta a wa yii, lo yẹ ka fun, Baba wa Bọla Ahmed Tinubu, awa ko ti ri eeyan kan to tọ lati dupo yatọ si wọn. Ko si ẹni ti nnkan rere ko wuu,ṣugbọn ninu iyẹwu ẹ, o gbọdọ le gbe ara ẹ sori osuwọn.

''Awa o mọ ahesọ o, eyi tawa mọ ni pe Baba wa Bọla Ahmed Tinubu lawa n tẹle, Ohun si ni a gbaruku ti, Ọlọrun a fun wọn ni alaafia ati ẹmi gungun, wọn yoo depo naa."

Nipa wahala to n waye ninu ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Eko, Ọladẹjọ sọ pe:
''Se ẹ ri wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ o daa lori ailekoara ẹni nijanu, laarin ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ, beeyan ba ṣe le finu findọ sọ pe oun fẹẹ darapọ, yala ninu ẹgbẹ oṣelu, ijọsin tabi ẹlẹgbẹjẹgbẹ, itumọ to ni ni pe irufẹ eeyan bẹẹ ṣetan lati  huwa pọ ni ibamu ofin to jẹ ti ọmọ ẹgbẹ ati ofin ti wọn ba fi le lẹ.

"Bi a ba sọ pe o di ọmọ ẹgbẹ naa tan,  to wa ni iwa ko tẹ mi lọrun lo fẹẹ maa hu, o ku diẹ kaato, ko si le ṣiṣẹ lawujọ eeyan, koda lawujọ ẹranko gan-an, gbogbo aye lo bọwọ fun Kiniun oloola iju."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI