Bí wọ́n bá sọ pé kí n wá gba abẹ́rẹ́ Kòrónà lẹ́ẹ̀mẹwàá, mo ti ṣetán - Pasitọ Adébóyè pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 3, 2021

Bí wọ́n bá sọ pé kí n wá gba abẹ́rẹ́ Kòrónà lẹ́ẹ̀mẹwàá, mo ti ṣetán - Pasitọ Adébóyè pariwo síta


Alaṣẹ ati oludari ijọ Ridiimu, The General Overseer of the Redeemed Christian Church of God kaakiri agbaye, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye ti sọ pe ko si nnkan to le di oun lọwọ lati gba abẹrẹ ajesara to n dena ajakale arun Korona, niwọn igba to ba ti nii ṣe pẹlu ijeere ọkan awọn eeyan.
 
Ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, iyẹn ọjọ Ẹti, Furaidee, ijẹta ni Baba Adeboye tawọn eeyan tun n pe ni Daddy G.O sọrọ yii jade nibi ipade adura oloṣooṣu ti Holy Ghost Congress ti wọn maa n ṣe ninu ijọ naa to wa lopopona marọsẹ Eko si Ibadan.
 
Pasitọ Adeboye lakooko to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe oun ko da ẹnikẹni duro lati lọ gba abẹrẹ korona, niwọn igba ti wọn ba mọ pe o ba aagọ ara wọn mu.
 
Ninu ọrọ rẹ, Baba Adeboye sọ pe:
 
"Mi o sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe gba abẹrẹ korona, ẹ ko tii gbọ nnkan to jọ bẹẹ ri lẹnu mi. Dipo ki ẹ maa gbe ninu ibẹru tabi iyemeji, ẹ lọ gba abẹrẹ korona. Bi ẹ ba nigbagbọ wi pe gbigba abẹrẹ naa lo maa jẹ ki ọkan yin balẹ, ẹ le lọ gba a.
 
"Baba, ṣe ohun ti ẹ n sọ ni pe ẹyin naa le gba abẹrẹ korona? Bi awọn orilẹ-ede kan ba wa lagbaye, ti wọn sọ pe mi o le wa sibẹ lati waasu nitori pe mi o gba bẹrẹ korona, ohunkohun ni mo le ṣe fun Jesu Kristi.
 
 
"To ba jẹ gbigba abẹrẹ korona lo maa di mi lọwọ ohun ti Ọlọrun pe mi fun, bi wọn ba sọ pe ki n wa gba abẹrẹ naa lẹẹmẹwaa, mo ti ṣetan lati gba a."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI