Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ baba arugbo ẹni ọdun merinlelọgọta kan, Ajayi Awẹ lori ẹsun wi pe o fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹfa to jẹ ọmọ-ọmọ rẹ.
Agbegbe ti wọn pe B/98 Daja Ajowa-Akoko, to wa nijọba ibilẹ Ariwa Akoko, ipinlẹ Ondo niṣẹlẹ ọhun ti waye laipẹ yii.
Iya ọmọ naa, Arabinrin Fatimah Ọbademi, la gbọ pe o lọ fọrọ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Okeagbe-Akoko leti wi pe Ajayi fipa ja ibale ọmọ oun, ọmọ ọdun mẹfa, ti wọn si sare lọ gbe e.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, DSP Funmi Ọdunlami sọ pe Ajayi ti wa lọgba wọn, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo, ati pe awọn ti gbe ọmọ naa lọ si ọsibitu.
Ọdunlami sọ pe Ajayi yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii.
No comments:
Post a Comment