Ọwọ ileeṣẹ aabo ara-ẹni-laabo-ilu, tii ṣe Sifu Difẹnsi nipinlẹ Ondo ti tẹ baale ile, ẹni ọdun mẹrinlelogoji kan, Ayọdele Ige ti wọn sọ pe o lu awọn to n wa iṣẹ ni jibiti owo to din diẹ ni miliọnu meji naira.
AWIKONKO gbọ pe ogbologbo ni Ayọdele ninu iwa jibiti nipinlẹ Ondo ati agbegbe ẹ, to si jẹ iṣẹ ẹtan lo fi n lu awọn eeyan ni jibiti, ko to di pe iṣu dilẹ lẹyin asunṣujẹ ẹ laipẹ yii.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe o ti pẹ ti awọn oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi ti n wa Ayọdele, ti wọn si ti fi orukọ rẹ sita wi pe ki ẹnikẹni to ba rii tete ta wọn lolobo, iyẹn nitori pe oriṣiriṣi ẹsun lawọn eeyan ti fi kan an lọdọ wọn.
Wọn ni eeyan mọkandinlogun ni Ayọdele to n gbe ni Okuta Elerinla Estate, nilu Akurẹ lu ni jibiti owo naa to jẹ N1.9m.
Nigba ti wọn foju rẹ han fawọn akọroyin ni olu ileeṣẹ Sifu Difẹnsi to wa lagbegbe Alagbaka nilu Akurẹ, Ayọdele sọ pe oun lawọn to maa n ta oun lolobo nipa awọn to n wa iṣẹ, ati pe oun tun ni awọn ọga gba lẹka oṣiṣẹ ijọba to maa n ba oun pari iṣẹ jibiti naa.
O sọ pe aaarin oṣu kọkanla, ọdun 2019 si oṣu karun-un, ọdun 2020 loun fi lu jibiti owo naa, lai mọ pe aṣiri maa pada tu sita, ti ọwọ yoo si tẹ oun.
Hammẹd Abọdunrin Abubakar, to jẹ ọga agba fun ileeṣẹ Sifu Difẹnsi ninu ọrọ rẹ sọ pe o ti di dandan ki Ayọdele foju ba ile-ẹjọ.
No comments:
Post a Comment