Inu idaamu ati iporuru ọkan lawọn mọlẹbi ati ọrẹ gbajugbaja olori ọdọ kan nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Ọlamilekan Ogunnuga wa titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan, lori bi wọn ṣe lawọn ajinigbe jii gbe salọ, ti wọn si n beere ọgbọn miliọnu naira, ko to di pe wọn tu u silẹ layọ ati alaafia.
Ọjọbọ, Tọside, iyẹn ọjọ keje, oṣu yii la gbọ pe wọn ji Kọmureedi Ogunnuga, ẹni to jẹ olori ọdọ lapapọ fun ẹgbẹ National Youth Council of Nigeria (NYCN) nijọba ibilẹ Odogbolu, ipinlẹ Ogun gbe.
Agbegbe Ogere to wa nijọba ibilẹ Ikẹnnẹ la gbọ pe wọn ti ji Ogunnuga gbe lakooko to n bọ lati irin-ajo to lọ nilu Ibadan. Wọn ni ṣe lawọn ajinigbe ọhun tẹle mọto rẹ lẹyin, ko to di pe wọn daa duro lojiji, ti wọn si yọ ibọn sii
Alaga ẹgbẹ NYCN nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Abduljabar Ayelaagbe lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lọjọ Aiku, Sannde ana, to si lawọn ajinigbe naa ti ranṣẹ sawọn mọlẹbi Ogunnuga wi pe ki wọn san ọgbọn miliọnu naira lati fi gba a silẹ.
Ayelaagbe sọ pe awọn to ri mọto rẹ lẹgbẹ igbo nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaide ni wọn jẹ kawọn eeyan mọ pe wọn ti ji ọkunrin naa, paapaa nigba tawọn ajinigbe naa tun pe, ti wọn si n beere owo nla.
O sọ pe ọkunrin to ri ohun to ṣẹlẹ nigba ti wọn ji Ogunnuga gbe lo gbe mọto naa, ti awọn ọlọpaa si gba a lọwọ ẹ, koda,, ti wọn tun ti ọkunrin naa mọle fun iwadii. O jẹ ko di mimọ pe ni kete ti wọn ji Ogunnuga gbe loun pinnu lati gbe mọto naa kuro nibẹ.
No comments:
Post a Comment