Ọjọ manigbagbe lọjọ Aje, Mọnde, ana, ọjọ kẹrin, oṣu kẹwaa yii tun jẹ ninu itan awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ Kwara, lori bi wọn ṣe gba iwe igbega lẹnu iṣẹ, ti wọn si tun gba owo oṣu ajẹẹlẹ ọdun mẹrin wọn.
Awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ti ko din ni ẹgbẹrun meje aabọ, iyẹn 7,885 ni wọn gba iwe igbega wọn lẹnu iṣẹ, ti awọn miran ti wọn ti gba igbega lati ọdun 2018 naa si gba owo oṣu to tọ si wọn latigba naa.
Iwe igbega naa la gbọ pe o jẹ ti ọdun 2019, 2020 ati 2021.
Nibẹ ni gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti jẹ ko ye gbogbo awọn oṣiṣẹ naa wi pe igbayegbadun awọn oṣiṣẹ lo jẹ ijọba oun logun, idi niyi toun yoo fi maa wa gbogbo ọna lati dun wọn ninu.
No comments:
Post a Comment