Ọkan pataki lara awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Ogun, Oloye Olumide Aderinokun ti sọ pe ipade gbogboogbo ẹgbẹ wọn to waye kaakiri orilẹ-ede Naijiria ti fi àpẹẹrẹ rere lelẹ wi pe ẹgbẹ naa yoo gba ijọba pada lọdun 2023.
Aderinokun, ẹni to jẹ Akinruyiwa tilu Owu-Abẹokuta lo sọrọ idaniloju naa lonii ọjọ Aiku, Sannde, to si ni gbogbo eto lo ti fẹẹ pari fun idibo apapọ ọdun 2023.
O ni irin ajo lati gba orilẹ-ede Naijiria kuro lọwọ awọn to n waa lọ si oko iparun lọdun 2023 ti bẹrẹ fun ẹgbẹ PDP, to si lawọn yoo tubọ tẹra mọ iṣẹ lati ja ajaye.
Aderinokun tẹsiwaju pe bi ipade gbogboogbo wọn ṣe waye, ti awọn oloye tuntun dide lati tukọ ẹgbẹ naa, ti fi han daju pe ko si wahala mọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, bi ko ṣe pe iṣọkan ti pada jọba.
Awọn oloye ẹgbẹ mọkanlelogun ni wọn fẹẹ ṣakoso ẹgbẹ naa bayii, eyi ti mẹta ninu awọn to gbe apoti ti yege idibo, ti awọn mejidinlogun yooku si wọle lai ni alatako kankan.
No comments:
Post a Comment