Gomina Dapọ Abiọdun ti fọkan gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun balẹ wi pe atunṣe ti yoo mu irọrun ba igbokegbodo ọkọ fawọn araalu ni yoo bẹrẹ lonii, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karundinlọgbọn.
Dapọ Abiọdun lo sọrọ yii nibi abẹwo to ṣe lọ si awọn agbegbe naa bii Sango/Jọju si Ọta, to si ri bi ibẹ ṣe bajẹ to kọja sisọ.
O ni gbogbo awọn to n gba oju ọna naa kọja ni wọn yoo bẹrẹ sii rẹrin ayọ, nitori pe atunṣe ti wọn fẹẹ bẹrẹ naa yoo mu alaafia deba igbokegbodo ọkọ.
No comments:
Post a Comment