Wọ́n ti ju Olúwatófúnmi, ọmọ ogún ọdún sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn àfipá bá ọmọ kékeré láṣepọ̀ l'Óṣogbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 21, 2021

Wọ́n ti ju Olúwatófúnmi, ọmọ ogún ọdún sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn àfipá bá ọmọ kékeré láṣepọ̀ l'Óṣogbo


Ile-ẹjọ Majisireeti tilu Oṣogbo ti paṣẹ pe ki wọn si lọ fi Tọpẹ Oluwatofunmi, ọmọ ogun ọdun pamọ sọgba ẹwọn lori ẹsun wi pe o fipa ba ọmọ kekere kan laṣepọ niluu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun.
 
Onidajọ Oluṣẹgun Ayilara lo sọ pe ki Oluwatofunmi ṣi lọ maa gbadun ara rẹ lọgba ẹwọn tilu Ileṣa titi di ọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ti igbẹjọ yoo tun pada waye.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ to kọja yii ni Oluwatofunmi ṣiṣẹ ibi naa lojule keje, adugbo Abidogun, Ọta-Ẹfun nilu Oṣogbo.
 
Agbẹjọro ọlọpaa, temitọpẹ Fatọba to ṣalaye niwaju ile-ẹjọ sọ pe ṣe ni Oluwatofunmi fipa ba ọmọdebinrin naa to pe orukọ rẹ ni Fẹranmi Aroyehan laṣepọ.
 
Bo tilẹ jẹ pẹ Oluwatofunmi sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun,ti agbẹjọro rẹ, Ọladipupọ Tunbọsun, si bẹbẹ pe ki ile-ẹjọ naa faaye silẹ lati gba beeli onibara oun, wi pe o lawọn oniduro to yọranti, ṣugbọn ti agbẹjọro ọlọpaa sọ pe o ṣeeṣe ko salọ, bi aaye beeli ba yọ silẹ fun un.
 
Eyi gan-an lo jẹ ki Onidajọ Ayilara paṣẹ pe ki wọn lọ fi Oluwatofunmi pamọ sọgba ẹwọn titi digba ti igbẹjọ yoo fi tẹsiwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI