Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe gbogbo awọn agbaṣẹ́ṣe tọwọ ba tẹ wi pe wọn n ṣiṣẹ ti ko kun oju oṣuwọn to owo akanṣe iṣẹ ti wọn gba ni wọn yoo fi oju winna ofin.
Wọn ni bi wọn ba gba iṣẹ naa lọwọ wọn tan, wọn yoo tun gbe orukọ wọn sinu iwe dudu (Blacklist), lati jẹ ki gbogbo agbaye mọ pe jibiti ni wọn n fi orukọ ileeṣẹ naa lu.
Alaga ajọ SUBEB, State Universal Basic Education nipinlẹ naa, Ọjọgbọn Shehu Raheem Adaramaja lo ṣe ikilọ nla yii fun gbogbo awọn agbaṣẹṣe ninu akanṣe iṣẹ UBEC/SUBEB to n lọ lọwọ.
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni aṣiri awọn agbaṣẹṣe kan tu si ajọ SUBEB lọwọ wi pe iṣẹ ko kun oju oṣuwọn ni wọn n ṣe, ti wọn si ni ki wọn tun iṣẹ naa ṣe lai fi akoko ṣofo.
AWIKONKO gbọ pe akanṣe atunṣe awọn ile ẹkọ ti ko din ni ẹgbẹta (600) ni ajọ SUBEB n ṣagbatẹru ẹ lọwọlọwọ. No
Various renovation or rehabilitation works are ongoing across 600 schools in Kwara State — thanks to the state recently accessing seven-year matching grants from the Universal Basic Education Commission (UBEC).
Adaramaja nigba to n sọrọ labule Gorobani to wa nijọba ibilẹ Kaiama sọ pe awọn ko ni ro o lẹẹmeji lati fiya to tọ jẹ agbaṣẹṣe tọwọ ba tẹ wi pe ṣe lo fẹẹ lu ijọba ni jibiti pẹlu ajanbaku iṣẹ.
No comments:
Post a Comment