Pupọ awọn to ri aworan gbajugbaja oṣere adẹrinpoṣonu nni, Ọlaniyi Afọnja, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Sanyẹri lo n ṣe ni kayeefi nla pẹlu bo ṣe di arugbo ojiji.
Inu fiimu agbelewo tuntun kan, Oke Agba to fẹẹ gbe jade lo ti di arugbo naa, taa si gbọ pe wọn ṣẹṣẹ pari akojọpọ rẹ ni.
Ṣẹgun Ogungbe ni wọn lo dari fiimu ọhun, ti ọpọ awọn agba ati gbajugbaja oṣere si wa nibẹ gẹgẹ bi akopa.
Fiimu yii ni wọn sọ pe yoo gun ori atẹ laipẹ.
Diẹ ree lara awọn aworan Sanyẹri ninu fiimu naa, ti wọn ni yoo kun fun ọgbọn ati ẹkọ.
No comments:
Post a Comment