Ọrọ awọn agba kan to sọ wi pe 'ọjọ gbogbo ni ti ole, ọjọ kan ṣoṣo bayii ni ti olohun' lo lọ ni ibamu pẹlu bọwọ ọlọpaa ṣe tẹ gendekunrin kan, Rotimi Ojugbelẹ laaarọ oni, ọjọ Aje, Mọnde lasiko to n bọ lati ibi to ti lọ jale.
Oju ọna Ilaro si Owode Yewa, ipinlẹ Ogun lọwọ palaba Ojugbelẹ ti segi ni nnkan bi aago mẹfa aabọ aarọ oni.
Asiko ti wọn loun pẹlu ọrẹ rẹ kan, toun ti na papa bora n bọ lati ibi ti wọn ti lọ jale lọwọ ti tẹ ẹ.
AWIKONKO gbọ pe ori ọkada lawọn mejeeji wa nigba ti awọn ọlọpaa da wọn duro. Bi wọn ṣe da wọn duro la gbọ pe ẹnikeji ti sare bọ silẹ lori ọkada, to si salọ.
Oju ẹsẹ lawọn ọlọpaa ti sare le Ojugbele mu, ko ma ba a salọ. Bi wọn ṣe yẹ baagi to gbe dani wo, lo jẹ pe ibọn, ọta ibọn loriṣiriṣi lo wa nibẹ.
Yatọ si eyi, wọn tun ba foonu Samsung galaxy S8, foonu kekere Intel ati egboogi oloro bii igbo, to fi mọ owo ni wọn tun ba ninu baagi ọhun.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Awolọwọ Ajogun ti wa paṣẹ pe ki iwadii tẹsiwaju lori Ojugbelẹ lati le ri ẹnikan yooku rẹ mu, ki wọn le foju ba ile-ẹjọ.
No comments:
Post a Comment