Laarọ oni, Ọjọru, Wẹside, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan, Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ gbe iwe eto iṣuna ọdun 2022 lọ siwaju ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa.
Eto iṣuna ọhun to pe ni 'Eto iṣuna idagbasoke ati Anfaani' (Budget of Growth and Opportunities) la gbọ pe owo to din diẹ ni ọọdunrun biliọnu (N294.5billion) naira ni wọn fẹẹ na lọdun 2022 to n bọ lọna.
Igba akọkọ ree ninu itan ipinlẹ Oyọ ti gomina yoo maa gbe iru eto iṣuna olowo nla yii lọ siwaju ile igbimọ aṣofin, eyi ti wọn sọ pe akanṣẹ iṣẹ idagbasoke lo mu eyi to pọ ju, pẹlu ida mẹtalelọgbọn din diẹ (32.83%), ti eto ẹkọ si mu ida mejidinlogun le diẹ (18.37%), nigba ti eto ilera ati iṣẹ agbẹ mu ida mẹfa din diẹ ati mẹrin din diẹ (5.9% ati 3.84%).
Nibẹ lo ti ṣalaye bi wọn ṣe ṣeto iṣuna ọdun 2021 ti a wa yii, ati ibi ti iṣẹ de duro, to si ni ọdun 2022 yoo tun jẹ ọdun ti ohun rere yoo ṣẹlẹ.
E ka ọrọ Gomina Makinde nibi yii: ỌRỌ GOMINA ṢEYI MAKINDE NIBI ETO IṢUNA ỌDUN 2022 FUN IPINLẸ ỌYỌ, TO WAYE LONII
Diẹ lara awọn fọto bi eto naa ṣe lọ si ree:
No comments:
Post a Comment