Ọwa Ajero tilu Ijero, Ọba Joseph Adebayọ, ati Olowu Kuta, Ọba Oyelude Makama ti tu aṣiri ọna abayọ to le mu ki orilẹ-ede Naijiria ni idagbasoke ti awọn eeyan ti n reti lati ọjọ pipẹ sẹyin.
Awọn ọba mejeeji yii sọ pe bi wọn ba ṣe atunto Naijiria lọna to yẹ, lai fi ti ẹlẹyamẹya ṣe, gbogbo araalu ni wọn yoo bọ sinu igbadun ati ọla nla.
Wọn ni bi wọn ba ṣe atunto orilẹ-ede yii pẹlu ifẹ ati otitọ, ilọsiwaju ati idagbasoke to lọọrin lawọn eeyan yoo ri, ti yoo si mu inu wọn dun, bo ti tọ ati bo ti yẹ.
Ọwa Ajero ati Olowu Kuta tun sọ pe bi atunto naa ba waye tan, gbogbo aini ifọkanbalẹ, aisi eto aabo to ti n ṣẹlẹ lati igba pipẹ sẹyin yoo dopin, ti yoo si dohun igbagbe.
Nibi ipade ẹgbẹ ọmọ Yoruba kan ti wọn pe ara wọn ni Yoruba Global Council ti wọn ṣe laipẹ yi lawọn ọba alaye mejeeji yii ti sọrọ naa jade.
No comments:
Post a Comment