Olori ajijangbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho ti sọ pe orilẹ-ede Oduduwa tawọn foju sọna fun yoo waye.
Igboho sọ pe lara awọn idi pataki ti orilẹ-ede Yoruba gbọdọ fi da duro ni lati maa jẹ anfaani ina mọnamọna to ja geere lai ni idiwọ kankan ninu bi i ti ilẹ olominira Bẹnnẹ.
Siwaju si i lo sọ pe pataki ni odaduro ilẹ Yoruba gbọdọ jẹ, ki wọn si yapa kuro lara Naijiria, bi awọn eeyan ba n fẹ ilọsiwaju.
Igboho lo sọrọ naa laipẹ ninu atẹjade to gbe sita lati ọwọ agbẹnusọ rẹ lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Ọlayọmi Koiki
O ni Igboho gbagbọ pe laipẹ, Naijiria yoo dohun igbagbe, nitori pe orilẹ-ede Yoruba yoo dide lati wa si imuṣẹ.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Mo gba iroyin lati ọdọ Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti inagijẹ rẹ n jẹ Igboho nipasẹ agbẹjọro rẹ lorilẹ-ede Bẹnnẹ, Oluṣẹgun Falọla wi pe Igboho ṣi duro lori ipinnu rẹ nipa idasilẹ ilẹ Yoruba, ati pe ko nigbagbọ pe Naijiria ṣi wa mọ.
"O gbagbọ gẹgẹ bi ọmọ Yoruba, ati ẹni to sunmọ araalu wi pe Yoruba ni lati da duro funra wọn gẹgẹ bi orilẹ-ede
"O sọ pe ka wo ilẹ olominira Bẹnnẹ bi wọn ṣe n jẹ anfaani ina mọnamọna lai ṣẹju loorekoore. Ohun ti a n fẹ ree ninu idasilẹ orilẹ-ede Yoruba ti a n beere fun, ti o si maa tẹ wa lọwọ laipẹ.
"Bẹẹ lo tun tẹnumọ ọrọ rẹ wi pe ko si nnkan to n jẹ ipadasẹyin ninu ọrọ idasilẹ orilẹ-ede Yoruba."
No comments:
Post a Comment