Orí kó àwọn márùn-ún yọ lọ́wọ́ ikú òjijì l'Abẹ́òkúta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 15, 2021

Orí kó àwọn márùn-ún yọ lọ́wọ́ ikú òjijì l'Abẹ́òkúta


Bi kii ba a ṣe ori to ko awọn marun-un kan yọ lọwọ ikuku ojiji ni, boya ki ba ti padanu ẹmi rẹ sinu ijamba mọto lopopona Abẹokuta silu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun.

Iwaju gbagede ọgba PMB Estate to wa ni Kọbapẹ, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode niṣẹlẹ ọhun ti waye.
 
A gbọ pe mọto ayọkẹlẹ Toyota Camry ti nọmba idanimọ rẹ jẹ 205 DGB 636 AA lo kagbako ijamba naa, nigba ti wọn sọ pe ijanu mọto naa daṣẹ silẹ lori ere asapajude, to si gbokiti.
 
Awọn ti ko din ni marun-un ni wọn wa ninu mọto yii, obinrin mẹta ati ọkunrin meji.
 
Obinrin kan ṣoṣo ninu wọn la gbọ pe o farapa gidi, to si jẹ pe awọn ẹṣọ aabo oju popona tipinlẹ Ogun, TRACE ni wọn sare dooal ẹmi ẹ lọ si ọsibitu nibi to ti n gba itọju lọwọ.





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI